Good Afternoon I need the Oriki (Praise song) of this villages in Abeokuta,Ogun State Nigeria.... It's for a documentary I am working on. 1. Ake 2. Owu 3. Ibara 4. Igbeyin 5. Remo 6. Mowe.
ORIKI OWU*** ** Omo olowu oduru omo a fegbe sere owu kii ranro, sugbon awii menu kuro no towu popondo l'ara owu nje aje f'ajaga bo'run Awa lomo olowu iji Omo olowu Oduru,awa lomo asunkungbade aforogboye atewo lafi gboye lowu tiwa awa lomo amolese bi alari alari molese ti nwole omo oba nile aro Bi ase to lansoge to,bi baba wa se lowo to lansoge to omo owu ki ran oro awimenu kuro ntowu awa lomo woyira ka ma ba ra erukeru nitori erukeru ama bi lala lenu Owu l’a ko da o Bi e d’owu E beere wo Owu l’ako da o Bi e de’fe E bere wo o Owu l’a ko da o Bi e de’le E kaa ‘tan wo Owu l’a ko da o Bi e de’le E ka ‘tan wo o Oriki Iremo/ Remo Omo Imole Omo gbogbo ebora Omo Imole ti i j’ ogede agbagba Omo eluku ara iraye Omo egungun, Omo agemo Omo egbaagbeje orisa Omo obalufon Omo imole to k’ ori omo e s’ odo Bo pon re, akun eje Ai pon re, akun efa Egungun a ri ‘mo yo Ebire lo ni Ile Iremo Ibi o ba da ebo nu si Aguntan lo o gba B oo r’ aguntan B oo r’ eyele nje a ma a lo A ns’oro, a nsesa A ngbe ‘gba aje re Iremo – Omo Yeloja Oloja nta abari, oja nta ekuru Omo imole ti i j’ ogede agbagba.
Oriki of Ake (Abeokuta)
OmAra ake majo, majo jo lofa,
jojo lofa gbogbo dindin eni.
Omo ajo gberu ma majo gbeko
nitori eru nii sini,
Eko kii sin'yan
Omo oloka meridin logun
omo elere mefa
omo boba le peja ko peja
omo boba leparo ko paro ogongon lo gbodopa omo alake mesi ara ake majo arake majo o